Ijọba ipinlẹ Ogun l'opin ọsẹ to n pari lọ yii ti bu ọwọ lu ileeṣẹ to n ta ilẹ, ile ati dukia, iyẹn Pelican Valley Estate lati maa ṣiṣẹ agbẹ lori awọn ilẹ wọn, eyi ti a mọ si Pelican Farm Estate.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni lẹyin ọpọlọpọ agbeyẹwo ti ijọba ṣe nipa ileeṣẹ Pelican, paapaa lori awọn ilẹ wọn lo fa a ti ijọba ṣe fun wọn niwe aṣẹ lati ṣiṣẹ agbẹ, eyi ti yoo jẹ ki ounjẹ pọ yanturu niluu.
Agbegbe ọhun la gbọ pe yoo fun gbogbo awọn ta b n gbe nibẹ yoo ti ni afaani lati da oko lai ni idiwọ ati idena, eyi ti yoo si tun mu idagbasoke ati ilọsiwaju eto ọrọ aje.
Nigba to n sọrọ, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ to jẹ alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Pelican sọ pe gbogbo eto lo ti pari fun iṣẹ lati bẹrẹ nitori pe awọn ti mura silẹ fun igbesẹ t'awọn n gbe yii.
O lawọn ti tọwọ bọwe adehun pẹlu ileṣẹ to n ri sọrọ iwadii nipa iṣẹ ọgbin Kokoo, Nigeria Ministry of Cocoa Research, lati le wa yẹ ilẹ wọn wo, to si ni wọn ṣee, wọn si rii pe o dara fun ọgbin Kokoo.
Bakan naa lo sọ pe awọn yoo daabobo awọn oko wọn lọwọ ina ati awọn Fulani darandaran, to si ni idunnu lo jẹ fawọn pe awọn ko le ni ipenija kankan lọdọ awọn Fulani darandaran, nitori pe awọ maluu kii jẹ Kokoo, eyi to ni yoo jẹ anfaani nla fun wọn, ati agbegbe naa ko si Fulani darandaran nibẹ.
O ni akọkọ iru ẹ leyi yoo jẹ nipinlẹ Ogun, nitori pe ijọba lo bu ọwọ lu, ti wọn si ti ya bi eto ile kikọ ati iṣẹ agbẹ yoo ṣe lọ nibẹ. O lẹsẹkẹsẹ ti ijọba ti fọnte lu wọn lawọn ti bẹrẹ iṣẹ f'awọn onibara wọn lati wa ba wọn dowopọ.
Nigba to n sọrọ lori anfaani tawọn onibara wọn yoo jẹ lori ilẹ yii, o ni ọpọ anfaani lo wa nibẹ, nitori pe o maa rọrun lati lo, ati pe ohunkohun teeyan ba fẹẹ fi ṣe ni yoo loo fun lọjọ iwaju pẹlu irọrun. O ni Kokoo yoo lo aadọrin si ọgọrin ọdun, ti yoo si jẹ ogun gidi t'awọn to n bọ lẹyin yoo jẹ anfaani rẹ, lati fi ṣe ohun ti wọn ba n fẹ.
No comments:
Post a Comment