Ìgbéyàwó mi tó dàrú kò kan ayé - Wùmí Toríọlá, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 24, 2023

Ìgbéyàwó mi tó dàrú kò kan ayé - Wùmí Toríọlá, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà


Gbajugbaja oṣerebinrin nni, Ọmọwumi Toriọla ti sọ pe igbeyawo oun to daru ko kan ẹnikẹni nitori pe ọrọ igbesi aye oun niyẹn.

Wumi Toriọla sọ pe ko si irọ tabi awuyewuye ninu wi pe oun pẹlu ọkọ oun ti pin gaari, nitori pe ibagbepọ wọn ko ṣiṣẹ mọ.

Bakan naa lo sọ pe kii ṣe pe oun jẹ alagidi iyawo nigba toun wa nile ọkọ oun, ati pe irọ to jinna si otitọ pọmbele ni.

“Oriṣiriṣi akọroyin ni wọn ti n fẹ gbọ ọrọ ẹnu mi tipẹtipẹ lori igbeyawo mi.

“Bẹẹni, otitọ ni pe igbeyawo wa ti fọriṣanpọn. Awa mejeeji ti lọ lọtọọtọ lati bi ọdun kan bayii. Ko ṣi ṣiṣẹ bi a ṣe lero ni. Ko si aaye fun ere, idi ree ti nko fi jẹ ki awọn ololufẹ mi mọ nipa ẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI