Gbogbo awọn agbaagba ati alẹnulọrọ niluu Ọpẹji to wa n'ijọba iibilẹ Ọdẹda, ipinlẹ Ogun ni wọn jade sita gbangba lati sọ pe ẹnikan ṣoṣo t'awọn nigbagbọ ẹ lati lọ ṣoju wọn nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun ni Olumide Aderinokun.
Wọn ni Aderinokun, ẹni to n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP) lawọn yoo ṣatilẹyin fun, ti wọn yoo si rii pe o ri ibo rẹpẹtẹ lati agbegbe wọn.
Yatọ si awọn agbaagba naa, ẹgbẹ awọn obinrin, ọmọde ati ọdọ ni wọn ko gbẹyin lati fi ọwọ sọya wi pe awọn n fẹ Aderinokun n'ipo.
Nibi ipade ti awọn eeyan naa ṣe pẹlu Aderinokun niluu Abẹokuta lọjọ Abamẹta, Satide ni wọn ti sọrọ idaniloju yii, ti wọn si lawọn ni lati fi ẹmi imoore han si ẹlẹyinju aanu mẹkunnu, nitori pe o mọ ibi ti bata ti n ta awọn araalu lẹsẹ.
Lara awọn agbaagba naa ni Seriki awọn Fulani niluu Ararọmi-Ọpẹji, Adamu Mohammed; Baalẹ awọn Fulani l'Ọpẹji, Abdullahi Babatunde, Baale awọn Egun, Dogbloue Martin atawọn miran.
Nibẹ ni wọn ti lawọn yoo fi ẹmi imoore han si Aderinokun, ẹni ti wọn lawọn ko le gbagbe ipa to ko ninu eto idagbasoke ṣe fun wọn lakoko eto idibo ọdun 2019.
Wọn loo tun opopona wọn ṣe, bẹẹ lo tun fun wọn ni ẹrọ amunawa tijọba ati omi ẹrọ igbalode to ṣe fun wọn. Wọn ni bawọn ba fun laaye lati lọ ṣoju wọn l'Abuja, yoo tun ṣe ju bẹẹ lọ fun wọn.
Nigba toun naa n dupẹ lọwọ awọn eeyan yii, Aderinokun ṣeleri wi pe oun ko ni ja wọn kulẹ, ati pe gbogbo ohun ti yoo ba mu idunnu ati ayọ wọle fun wọn loun yoo ṣe.
No comments:
Post a Comment