Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, lọjọ Tusidee, ọsẹ yii ti sọ pe gbogbo iranlọwọ to ba wa nikawọ oun, loun yoo ṣe lati rii pe gendekunrin, ọmọ ipinlẹ naa to ṣe baluu kekere to n ka aworan, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni 'Drone', ko le tubọ maa tẹsiwaju.
Aliyu Musa lorukọ ọmọkunrin naa ti wọn lo ṣẹṣẹ kẹkọọ jade nile ẹkọ girama.
Ṣaaju akoko naa ni Aliyu ti kọkọ ṣalabapade amugbalẹgbẹ gomina lori eto iṣẹ ọwọ igbalode (Creative Industries), Abdulgafar Ahmed ti ọpọ awọn eeyan mọ si Cute Abiọla niluu Ilọrin.
Drone naa ni wọn tun n pe ni Unmanned Aerial Vehicle (UAV).
Nigba to n sọrọ, AbdulRazaq ni idunnu nla lo jẹ foun lati ri ọkan lara awọn ọjọ ọla ipinlẹ naa to ti n gbe ohun rere ṣe, to si ni lara awọn pataki idi toun fi n gbe eto to n ṣanfaani f'awọn ọdọ kalẹ niyẹn.
“Ohun iwuri lo ṣe yii, a si ni lati lu ọ lọgọ ẹnu, ka gbe oṣuba kare fun ẹ. Iṣakoso wa maa n ri awọn ọdọ to ja fafa bii tiẹ, ti wọn le lo imọ wọn fun ohun to dara. Idi ree ti a fi n na owo gidi lati maa gbarukuti awọn ọdọ nipinlẹ yii.
“Ọpọ awọn iṣẹ wa ati ilana agbekalẹ wa lo jẹ pe nitori awọn ọdọ ni. A fẹẹ ko ipa rere nigbesi aye wọn, ki wọn le da si ọrọ idagbasoke pinlẹ yii, paapaa orileede yii.”
Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe oun yoo gbe gbogbo bukata eto ẹkọ ọmọkunrin naa lati le tubọ jẹ ki imọ rẹ maa gun oke sii.
Bakan naa lo sọ pe oun yoo ṣe iwanwọ lati rii pe o gba iwe aṣẹ ti yoo jẹ ki imọ rẹ maa tẹsiwaju nipa itẹwọgba ajọ agbaye.
No comments:
Post a Comment