Gbogbo Banki Naijiria ni yoo ṣilẹkun silẹ lọjọ Satide ati Sannde lati ṣe paṣipaarọ owo tuntun - CBN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, January 28, 2023

Gbogbo Banki Naijiria ni yoo ṣilẹkun silẹ lọjọ Satide ati Sannde lati ṣe paṣipaarọ owo tuntun - CBN


Banki agba orileede yii, Central Bank of Nigeria ti paṣẹ wi pe ki gbogbo banki ilẹ Naijiria ṣilẹkun wọn lọjọ Abamẹta, Satide oni, ọjọ kejidinlọgbọn, ati ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii.

Erongba CBN ni pe ki gbogbo awọn araalu ti wọn ba ni owo naira atijọ lọwọ lọ ṣe paṣipaarọ rẹ si owo naira tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ko jade, ṣaaju ọjọ ti nina owo atijọ naa yoo kasẹwọle.

Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kinni ti a wa yii ni CBN kede pe wọn yoo na awọn owo naira bii igba naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati ẹgbẹrun kan naira alalapapọ gbẹyin ni Naijiria.
 
Banki agba naa sọ pe gbogbo banki patapata ni wọn gbọdọ ṣilẹkun silẹ fawọn eeyan lati ṣe paṣipaarọ owo naa fun wọn lai si idaduro.

Bakan naa ni wọn sọ pe banki ti ko ba ṣilẹkun silẹ, tabi banki ti ko ba ṣe paṣpaarọ owo f'awọon to ba wa ni yoo jẹ iyan rẹ n'iṣu, ti yoo si fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.
 
Ile ifowopamọ GTBank ni ti wọn ti wa rọ gbogbo awọn onibara wọn lati waa ṣe paṣipaarọ owo wọn laari agogo mẹwaa aarọ si agogo mẹta ọsan, lawọn yoo fi ṣilẹkun lọjọ Abamẹta, Satide tii ṣe oni, ati ọjọ Aiku, Sannde, tii ṣe ọla.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI