Ọga ọlọpaa ẹkun ijọba ibilẹ Jahun to wa n'ipinlẹ Jigawa, SP Abubakar Musa ni iroyin ti fi to wa leti pe o ti dagbere f'aye lẹnu iṣẹ to yan laayo
A gbọ pe ṣe ni ọga ọlọpaa naa yọ ṣubu ninu ọfiisi rẹ, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa naa, DSP Lawan Shiisu Adamu lo f'idi iroyin naa mulẹ f'awọn akọroyin lopin ọsẹ to k'ọja yii.
O ni nnkan bi aago mẹsan alẹ, ọjọ Ẹti, Furaidee ni ọga ọlọpaa naa yọ ṣubu, to si gbabẹ gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra. Aisan kan lo sọ pe o kọlu oloogbe naa, ko to gbodi lara ẹ.
Adamu ni asiko ti Musa fẹ maa lọ sile, lẹyin iṣẹ ọjọ naa lo dagbere f'aye, to si l'awọn gbiyanju lati doola ẹmi ẹ, nipa sisare gbe e lọ si ọsibitu Rashid Shekoni, ṣugbọn ti wọn ko pa a, eyi lo mu kawọn tun gbe e lọ si ọsibitu Aminu Kano, nibi ti wọn ti sọ fun wọn pe ọkunrin naa ti ku.
Bakan naa, ọga agba pata fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Emmanuel Ekot Effiom ti ba mọlẹbi oloogbe naa kẹdun.
No comments:
Post a Comment