Emir ilu Dutse, Ṣanusi jade laye, ni Buhari ba sọrọ soke - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 31, 2023

Emir ilu Dutse, Ṣanusi jade laye, ni Buhari ba sọrọ soke


Ẹmir ilu Dutse to wa n'ipinlẹ Jigawa, Ọmọwe Nuhu Muhammad Sanusi ti jade laye, lẹni ọdun mejidinlọgọrin.
 
Ọmọwe Ṣanusi lo jade laye lonii, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee lẹyin aisan rampẹ ti wọn lo kọluu lojiji.
 
Ninu atẹjade ti amugbalẹgbẹ pataki fun gomina ipinlẹ naa lori ọrọ iroyin ori ayelujara, Auwalu Sankara gbe jade lonii, o ni ọsibitu kan niluu Abuja ni Ẹmir naa ku si.
 
Gomina ipinẹ Jigawa, Alaaji Muhammad Badaru Abubakar naa ti kọminu lori iku olori ilu naa, to si ni ọkan lara awọn opo to di ilu Dutse mu ni iku ti mu lọ lojiji mọ wọn lọwọ.
 
Abubakar ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi ẹni to ni ọgbọn, imọ ati oye nipa didari ilu, paapaa lẹka eto idagbasoke ilu, to si l'awọn yoo mọ lara wi pe baba naa ko si mọ.
 
Ọdun 1995 ni wọn yan Ọmọwe Muhammad Sanusi, iyẹn lakoko Oloogbe Colonel Ibrahim Aliyu.

Aarẹ Muhammadu Buhari nigba to n kẹdun iku Ọmọwe Ṣanusi, o ni ẹni t'awọn araalu nifẹẹ gidigidi ni oloogbe naa, nitori pe ipa to ko ninu eto idagbasoke ilu Dutse ko ṣee fọwọ rọ sẹyin

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI