Emi ko ku ooooo - Ojulowo Papa Ajasco pariwo sita faraye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 15, 2023

Emi ko ku ooooo - Ojulowo Papa Ajasco pariwo sita faraye


Gbajugbaja oṣere tiata adẹrinpoṣonu nni, Abiọdun Ayọyinka, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Papa Ajasco lo ti gba ori ikanni ayelujara lọ lati sọ pe oun ko ku, to si ni digbi lara oun le koko.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni iroyin na jade sita wi pe oṣere alawada nni, Fẹmi Ogunrombi ti awọn eeyan tun mọ si Papa Ajasco ti jade laye.

Ọpọ awọn iroyin ayelujara to gbe iroyin ọhun sita lo jẹ pe fọto Ọgbẹni Ayọyinka ni wọn lo, dipo fọto Ogunrombi to jade laye.

Fawọn ti ko ba mọ, Fẹmi Ogunrombi lo kopa Papa Ajasco laaarin ọdun 2015 si ọdun 2016.

Lọsan oni, ojulowo Papa Ajasco fúnra rẹ, Ayọyinka ti wa jade sita lati sọ fun gbogbo aye wi pe oun ko ku.

Ninu fọnran naa to tẹ AWIKONKO lọwọ, ni ọkunrin naa ti sọ pe
"Orukọ mi ni Abiọdun Ayọyinka, ẹni ti awọn eeyan mọ si Papa Ajasco. Emi ko ku o, mo ṣi wa laye, mo si fẹẹ dupẹ lọwọ ẹyin ololufẹ mi fun ifẹ yi . Mo dupẹ lọwọ yin."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI