Ẹgbẹ oṣelu APC n yin agbado sẹyin igba lasan ni, wọn maa lulẹ l'Ogun ni - Aderinokun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 8, 2023

Ẹgbẹ oṣelu APC n yin agbado sẹyin igba lasan ni, wọn maa lulẹ l'Ogun ni - Aderinokun


Oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin agba orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP n'ipinlẹ Ogun, Olumide Aderinokun ti sọ pe gbogbo igbesẹ ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC n gbe ninu eto idibo to n lọna yii, bi ẹni to n yin agbado sẹyin igba lasan ni.
 
Aderinokun, ẹni to n dije lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun lo sọrọ naa ninu atẹjade to gbe sita lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Taye Taiwo.
 
O ni ohun ti ko ye ẹgbẹ APC ni pe wọn ti kuna patapata laaarin gbungbun iinlẹ Ogun, paapaa gbogbo agbegbe ati igberiko ipinlẹ naa, ati pe ki wọn lọ maa palẹmọ ẹru wọn lati lọ sile, nitori pe eyi ti wọn ṣe ti to.
 
Ninu atejade naa to fi tako ọrọ ẹnikan ti wọn pe ni Onimọ-ẹrọ Akeem Adeṣina, eni to gbẹnusọ fun APC laipẹ yii wi pe oludije awọn lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun lawọn eeyan n fẹ lati lọ ṣoju wọn nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lọdun 2023 ti a wa yii.
 
Taiwo ninu atẹjade naa sọ pe ko si ẹni to mọ Shuaib Salisuri n'ipinlẹ Ogun, ati pe ko sẹni to gbọ orukọ rẹ, ati pe bawo ni awọn eeyan yoo ṣe maa sọrọ nipa ẹni ti wọn ko mọ.
 
O ni ẹnikan ṣoṣo t'awọn eeyan mọ, ti wọn si ti n gbọ orukọ rẹ tipẹ ni Oloye Olumide Aderinokun, ẹlẹyin aanu awọn mẹkunnu, ati oluranlọwọ awọn alaini.
 
Siwaju sii lo sọ pe iwaju ni Aderinokun wa si Shuaib nitori pe ko le tọka si iṣẹ akanṣe kan ṣoṣo tabi iranlọwọ to ti ṣe f'awọn eeyan to wa ni agbegbe rẹ, depodepo kaakiri ijọba ibilẹ mẹfa to wa ni aarin gbungbun ipinlẹ Ogun.
 
O ni Shuaib, ẹni to ti figba kan ri jẹ olori awọn oṣiṣẹ gomina ko le tọka si aṣeyọri kan to ti ṣe f'awọn eeyan, ati pe to ba ri bẹẹ, ko jade lati tọka ẹnikan ṣoṣo to ṣe iranwọ fun.

Bẹẹ lo sọ pe o ṣeni laanu wi pe awọn ti wọn ko ni iwa ati aṣeyọri ti wọn le tọka si, koda pẹlu ikuna wọn wa n sọ pe awọn fẹẹ jade lati du ipo, eyi to ni ala ti ko le ṣe rara ni.

"Awọn ara agbegbe ijọba ibilẹ Ọdeda, Ifọ, Ewekoro, Abẹokuta South, Abẹokuta North ati Ọbafẹmi-Owode ti ṣetan lati gba ọjọ iwaju wọn kuro lọwọ awọn to ti kuna ninu ijọba, paapaa pẹlu ileri oṣelu ti wọn n ṣe kaakiri."
 
Taiwo sọ siwaju pe ọkan ẹgbẹ PDP balẹ wi pe awọn araalu wa lẹyin wọn, nitori ti wọn ti ri awọn ipinnu rere ati idagbasoke ti wọn n gbe fun wọn, bi wọn ba wọle idibo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI