Ẹgba agbabọọlu Chelsea ni lati ṣe itusilẹ nla bi wọn ko ba fẹ ki aye gbagbe wọn - Wolii Ayọdele ju bọmbu ọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 12, 2023

Ẹgba agbabọọlu Chelsea ni lati ṣe itusilẹ nla bi wọn ko ba fẹ ki aye gbagbe wọn - Wolii Ayọdele ju bọmbu ọrọ


Alaṣẹ ati olori ijọ INRI Evangelical Spiritual, Wolii Elijah Ayọdele ti sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea nilo itusilẹ nla, nitori pe wọon ti gegun fun wọn.
 
Wolii Ayọdele lo sọrọ ọhun ninu fọnran kan to gbe sori ikanni TikTok rẹ lọsan oni, Wẹsidee.
 
O sọ peikọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti tan patapata, bi wọn ko ba si ṣọra, aye yoo pada gbagbe wọn patapata, fun idi eyi, o ni wọn gbọdọ ṣe itusilẹ.

“Chelsea ti tan. Bi wọn ko ba ṣọra, wọn ko nii gberi mọ. Awọn to ra Chelsea ni lati pada lọ gba ibunkun awọn to nii.

“Bi bẹẹ kọ, bi wọn ba ko awọn agbabọọlu ọwọ iwaju mẹwaa, ogun, atawọn to n di ọwọ ẹyin mu, to fi mọ gooli to dara julọ lagbaaye silẹ, ko le ṣiṣẹ, egun kan wa to n ja Chelsea lasiko yii.
 
“Mo ti sọ fun un yin, ẹ mu awọn ọrọ mi yii lokunkundun bi ẹ ba fẹẹ tẹsiwaju
, bi bẹẹ kọ Chelsea le lọ silẹ patapata, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni 'relegation'.

“Ẹgbẹ agbabọọ to ba koju Chelsea lasiko yii yoo lu wọn lalubami, wọn nilo itusilẹ ki wọn le dide giri si awọn ipenija to wa niwaju wọn.”

Bi ẹ ko ba mọ, ipo kẹwaa ni ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea wa lori tabili EPL lonii, Ọjọbọ, Tọsidee.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI