Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti tẹ gendekunrin, ọmọ ogun ọdun kan, Gaddafi Sagir lori ẹsun wi pe o gun iyawo baba rẹ, Rabi’atu Sagir pa toyun-toyun.
Yatọ si Rabi'atu, ẹni ọdun marundinlọgbọn ti Gaddafi gun pa, wọn lo fun ọmọ obinrin naa, ọmọ ọdun mẹjọ lọrun pa.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa gbe jade lati ọwọ alukoro wọn, Abdullahi Kiyawa Haruna lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹjọ, oṣu yii, o ni Gaddafi ti wa lahamọ awọn, nibi ti wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo lọwọ.
Haruna ni agbegbe Fadama to wa ni Rijiyar Quarters nijọba ibilẹ Ungogo niṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Abamẹta, Satide to kọja.
O ni irinṣẹ kan ti wọn n pe ni 'Screwdriver' ni Gaddafi fi gun iyawo baba rẹ naa pa, lẹyin eyi lo tun lọ fun ọmọ obinrin naa, Munawwara Sagir, ọmọ ọdun mẹjọ lọrun pa.
Alukoro naa sọ pe ọkọ obinrin naa, to tun jẹ baba Gaddafi, Ọgbẹni Sagir Yakubu lo lọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ni nnkan bi aago mọkanla aabọ.
No comments:
Post a Comment