Ẹ woju ọmọbinrin arẹwa to dawati lojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 8, 2023

Ẹ woju ọmọbinrin arẹwa to dawati lojiji


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii sẹni to le sọ pato ibi ti ọmọbinrin arẹwa ti ẹ n woju rẹ yii wa.
 
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ karun, oṣu kinni, ọdun ti a wa yii la gbọ pe ọmọbinrin naa, Rejoice Sarima Dike jade nile, ti ko si tii pada ri latigba naa.
 
AWIKONKO gbọ pe fasiti Madonna to wa nipinlẹ Rivers ni ọmọ ogun ọdun naa n lọ.
 
Wọn ni agbegbe kan ti wọn pe ni Atali Farm Estate, Eneke, Port Harcourt ni Rejoice n gbe, nnkan bi aago mẹjọ alẹ, ọjọ naa ni wọn rii gbẹyin.
 
Ẹnikẹni to ba kofiri rẹ, tabi mọ ohunkohun nipa ibi to wa, ko kan si awọn obi ati ẹgbọn rẹ lori awọn ẹrọ ibanisọrọ wọnyii 07034268865, 07083316134, 09010251931 tabi ki wọn lọ fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI