Ẹ wo oju baba agbalagba to ko arun HIV sara ọmọ ololufẹ rẹ, ọmọ ọdun mẹtadinlogun nipa ifipabanilopọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 29, 2023

Ẹ wo oju baba agbalagba to ko arun HIV sara ọmọ ololufẹ rẹ, ọmọ ọdun mẹtadinlogun nipa ifipabanilopọ


Epe rabandẹ-rabandẹ lawọn eeyan n ṣẹ fun baba agbalagba kan ti wọn lo n f'ipa ba ọmọ ololufẹ rẹ, ọmọ ọdun mẹtadinlogun laṣepọ karakara.
 
Baba radarada naa lo f'oju ba ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ibusa, ijọba ibilẹ Oshimili North, ipinlẹ Delta, l'ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2023.
 
Ọgba ẹwọn Ogwashi-uku, ipinlẹ naa la gbọ pe wọn ni ki baba naa ṣi ti lọ maa gbatẹgun titi di ọjọ igbẹjọ miran.
 
Gẹgẹ bi ajafẹtọ-ọmọniyan kan, Marvin Mordi ṣe fi to awọon eeyan leti, o sọ pe ọmọ ọdun mọkanla ni ọmọ naa wa, ti baba agbaaya ọhun ti n ba a laṣepọ.
 
Mordi sọ pe iya ọmọ naa ni baba yii n yan lale tipẹtipẹ, ko to di pe o tun lọ n ba ọmọ rẹ laṣepọ.
 
Ọkunrin naa tiẹ sọ pe mama ọmọ naa mọ pe oun n ba ọmọ oun laṣepọ.
 
Wọn ni baba naa tun lugbadi aarun kogboogun ti a mọ si HIV, to si ti ko o ran iya atọmọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI