Ọwọ ẹṣọ aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun ti tẹ Yisa Aderibigbe ti wọn lo fẹran lati maa fipa ba awọn ọmọ kekeeke laṣepọ kaakiri igboro ilu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun.
AWIKONKO gbọ pe ọmọ ọdun marun-un ati ọmọ ọdun meje kan ni Aderibigbe fipa ba laṣepọ ninu ile akọku kan to wa lagbegbe Ayepe, Oṣogbo, ko to di pe ọwọ tẹ ẹ l'Ọjọbọ, Tọsidee to kọja yii.
Ọga agba Amọtẹkun nipinlẹ naa, Ọgagun Bashir Adewinmbi, lo f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ni Aderibigbe ti wa lahamọ awọn nibi to ti n ṣalaye awọn iṣẹ ibi to ti ṣe sẹyin fun wọn.
Adewinmbi sọ pe Aderibigbe fẹran lati maa fipa ba awọn ọmọ kekeeke laṣepọ, ko to di pe ọwọ palaba ẹ segi.
No comments:
Post a Comment