Ẹ wa gbọ aṣiri iku to pa Baba Feyikọgbọn, agba oṣere tiata - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 10, 2023

Ẹ wa gbọ aṣiri iku to pa Baba Feyikọgbọn, agba oṣere tiata


Orin 'iku d'oro' lawọn ololufẹ fiimu agbelewo n kọ lonii, nigba ti wọn gbọ pe gbajugbaja oṣere tiata nni, Alagba Sunday Akinọla Mọgaji, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Baba Feyikọgbọn ti jade laye.

Baba Feyikogbọn jade laye lọjọ Aje ọsẹ yii, lẹni ọgọrin ọdun.

Agba oṣere ọhun ni o jẹ ilu mọ-ọn-ka lọdun 1980 ati 1990- pẹlu gbajugbaja ere sinima ọlọsẹ-ọsẹ ti a mọ si Feyikọgbọn

Sinima ọhun ni wọn maa ṣafihan rẹ lori amohunmaworan ti NTA Channel 7, to si lọ fun odiidi ọdun mẹtala.

Sulaimọn Arẹmu, olorin ati olowe, ti ọpọ mọ si Ajobiewe lo kede ipapoda agba oṣere naa lori ikanni ayelujara.

Bo ilẹ jẹ pe oriṣiriṣi l'awọn eeyan n sọ nipa ohun to ṣokunfa iku baba naa, sibẹ awọn kan sọ pe aisan ọjọ ogbo lo ṣe e, ko to di pe o gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
 
Bẹ o ba gbagbe, lọdun 2019 ni baba yii beere fun iranlọwọ owo lọwọ awọn araalu lẹyin to ni ipenija kidinrin.

Popular actor, "Baba Feyikogbon" dies at age 80
 
Lọdun naa, Baba Feyikọgbọn ni oun nilo Ọgbọn milọnu naira lati lọ si oke okun lati lọ ṣe itọju ara oun.

Wọn bi Baba Feyikogbon ni ọjọ kọkandilogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 1942.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI