Ẹ jẹ ka maa gba ifẹ ati iṣọkan to le mu orileede yii tẹsiwaju laaye - Gomina Abiọdun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 8, 2023

Ẹ jẹ ka maa gba ifẹ ati iṣọkan to le mu orileede yii tẹsiwaju laaye - Gomina Abiọdun


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti gba gbogbo awọn ọmọ orileede Naijiria, paapaa awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa lamọran lati maa gba ifẹ ati iṣọkan to le mu orileede yii tẹsiwaju laaye laaarin ara wọn.
 
Igbakeji gomina, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ Oyedele lo sọrọ naa l'ọjọ Ẹti, Furaide, nibi akanṣe adura irun Jumaati lati fi ṣe iranti ọjọ awọn akọni ọmọ ogun orileede yii ti wọn padanu ẹmi wọn sinu ijamba ogun, eyi to waye ni mọsalaṣi agba ti Kọbiti niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Abiọdun ni o ṣe pataki fun onikaluku lati maa beere lọwọ ara rẹ nipa idi ti a fi n gba iyapa ati ẹlẹyamẹya laaye, to si n jẹ ko di mimọ pe ile ti iyapa ba ti wa ko le duro.

O ni bi a ko ba di aala to wa laaarin ara wa, oogun awọn akọni ologun wa nii ni ipa rere kan, nitori pe niṣe la n gba iyapa laaye, to si lo di dandan lati maa gbe ni irẹpọ ati iṣọkan.
 
Bakan naa nigba to n sọrọ, Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, gba gbogbo awọn ọmọ Naijiria lamọran lati maa ranti awọn akọni orileede yii to ba ogun lọ ninu adura wọn ni gbogbo igba.
 
Alake ni awọn akọni naa ni wọn fi ẹmi wọn silẹ nitori ifẹ ti wọn ni si orileede Naijiria, to si gbadura pe oogun ati ẹjẹ wọn ko nii lọ lasan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI