Gomina banki agba lorileede Naijiria, Godwin Emefiele ti yọju sile igbimọ aṣoju-ṣofin orileede yii, o si ti jẹ ko ye wọn pe awọn yoo ṣi tubọ maa gba owo naira atijọ to wa nita wọle, iyẹn lẹyin gbedeke ọjọ ti wọn fi sita wi pe owo naa yoo kuro nilẹ.
Emefiele sọ pe asiko ṣi wa f'awọn ọmọ Naijiria lati lọ ko owo atijọ wọn si banki, lẹyin ọjọ kẹwaa, oṣu keji ọdun yii.
O sọrọ naa lakoko to ṣabẹwo s'awọn aṣoju-ṣofin lati dahun ibeere nipa owo naira tuntun to ṣẹṣẹ jade sita.
Bẹ o ba gbagbe, ile igbimọ aṣoju-ṣofin ti fẹsun kan Emefiele wi pe o tapa si abala ogun ninu iwe ofin to de CBN, ti wọn si lo gbọdọ wa a sọ ohun to ri.
“Lẹyin gbedeke ọjọ ti a fi sita, owo ti a n na tẹlẹ ko nii wulo mọ, ko si nii jẹ nina laaarin ilu mọ, ṣugbọn o tun sọ pe laaarin oṣu karun-un, oṣu kẹta, tabi oṣu keji lẹyin rẹ, koda titi di oṣu kẹfa, gbogbo owo atijọ ni banki yoo gba wọle.” Gbajabiamila lo sọrọ naa l'Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.
Nigba toun naa n sọrọ tiẹ, Emefiele to jẹ gomina CBN sọ pe oun ti gba gbogbo ohun ti ile igbimọ aṣoju-ṣofin fẹ wọle, gẹgẹ bi abala ogun ṣe sọ ninu iwe ofin CBN
“Abala ogun sọ pe bi a ko ba na owo atijọ mọ, wi pe a ṣi gbọdọ gba awọn owo naa pada. Mo duro lori ipinnu ile igbimọ aṣoju-ṣofin lori eyi” Emefiele lo sọ bẹẹ.
O tun tẹsiwaju pe
“Bi ẹ ba ṣi ni owo ti ẹ ko tii fi ranṣẹ si banki. O ti di dandan wi pe a maa fun un yin lanfaani lati ko wọn wa si banki agba lati gba a lọwọ yin. Yala ẹ fẹẹ ṣe paṣipaarọ ẹ, tabi ẹ fẹẹ san an si apo ifowopamọ yin - a maa fun un yin. Ẹ ko le padanu owo yin. Idaniloju ti mo n fun awọn ọmọ Naijiria ree.”
No comments:
Post a Comment