Bí onírúurú àtẹ̀jíṣẹ́ ìkíni ṣe ń wọlé wẹ́rẹ́ fún Igbákejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn lórí Ayẹyẹ Oríkádún rẹ̀ òní, ìyẹn Ọlọ́lájùlọ̀, Amojú-Ẹ̀rọ Noimot Sàlàkọ́-Oyèdélé tí ó ṣe ayẹyẹ Ọjọ́kẹtàdínláàádọ̀ta, Alága fún gbogbo àwọn Ọba Aláṣẹ Ìpínlẹ̀ Ògùn ní Ilẹ̀ Àwórì, Ọlọ́fin Àpésìn Olóde, Ọlọ́tà Ilẹ̀ Ọ̀tà, Orílẹ̀ Àwórì, Kábíèsí Aláyélúwà, Ọba Ọ̀jọ̀gbọ́n Adéyẹmí Abd'kabir Ọbalánlẹ́gẹ́ PhD, MCIPR, MPRII, FHEA (Lánlẹ́gẹ́ Ẹkùn Kejì, Àrolé Ìganmọdẹ) ṣe àpèjúwe Ọlọ́jọ́-Ìbí gẹ́gẹ́ bí "ẹni iyì, ẹni àpọ́nlé àti ẹni ẹyẹ ní ipò ọlá"
Nígbà tí Kábíèsí ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́jọ́-Ìbí náà, Aláyélúwà fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé, Igbákejì Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn jẹ́ ènìyàn pàtàkì, onínúure ẹ̀dá, obìnrin tí ó tayọ jù lọ nínú ìṣèlú, tí ó ti ṣe iṣẹ́ takuntakun, ní èyí tí ó sọ ọ́ di gbajúmọ̀ nínú ètò ẹbí rẹ̀, nínú ẹ̀sìn àti ìṣèlú tí ń ṣe.
Kábíèsí Ọlọ́tà wà níbi ayẹyẹ Oríkádún Igbákejì Gómìnà náà nígbà tí ó ń ṣe Àjọ̀dún Ọdún Kẹtàdínláàádọ́ta ní ilé rẹ̀ ní ìlú Abẹ́òkúta, Olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ògùn. Bákan náà ni Akọ̀wẹ́ Àgbà fún gbogbo Ìgbìmọ̀ àwọn Ọba Aláṣẹ Ilẹ̀ Àwórì kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú Kábíèsí lọ sí ibi ayẹyẹ náà, ìyẹn Kábíèsí Olú Ilẹ̀ Àgbárá, Orílẹ̀ Àwórì, Aláyélúwà (Amòfin) Ọba Jayéọlá Agúnbíadé LL. M, FCA.
Kí Èdùmàrè túbọ̀ bá fún Ọlọ́jọ́-Ìbí ní okun, agbára àti ẹ̀mí gígùn, kí ó sì dàgbà jù báyìí lọ láyé.
O ò lí kú lèwe, Àfàgbà
Ogbó, a tọ́
Orí ẹ á kànkè
Ọmọọba Adéyẹmí Sulaimon Olúṣesí
Fún: Ààfin Ọlọ́tà Ilẹ̀ Ọ̀tà,
Orílẹ̀ Àwórì
No comments:
Post a Comment