Aye ooooo! Papa Ajasco ti ku oooooo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 15, 2023

Aye ooooo! Papa Ajasco ti ku oooooo

Papa Ajasco tuntun to ku ree

Iroyin yajoyajo to tẹ AWIKONKO lọwọ ti sọ pe gbajugbaja oṣere adẹrinpoṣonu nni, Fẹmi Ogunrombi, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Papa Ajasco ti jade laye.
 
Ọkan pataki lara awọn oṣere tiata to pe ara rẹ ni Husseini Shuaibu lo gbe iroyin naa sori ikanni ayelujara ti Twitter rẹ laaarọ, oni, ọjọ Aiku, Sannde.

Bo tilẹ pe a ko tii le f'idi rẹ mulẹ pe ọkunrin naa ti jade laye titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ṣugbọn Husseini sọ pe ẹnikan to sunmọ Papa Ajasco lo sọ foun ni irọlẹ ana, Satide, Abamẹta.
 
Ogunrombi lo gbajumọ ninu ere atigbadegba ti Wale Adenuga, iyẹn Papa Ajasco.
 
Ogunrombi lo gba ipo Papa Ajasco lẹyin ti Abiọdun Ayọyinka to n kopa naa tẹlẹ loun ko ṣe mọ.
 
Kii ṣe Papa Ajasco, Abiọdun Ayọyinka lo ku o

Ẹkunrẹrẹ iroyin naa ṣi n bọ laipẹ...

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI