Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinẹ Niger ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lẹkunrẹrẹ lati rii pe ọwọ palaba awọn amookunṣeka kan to dana sun olori ijọ Katoliiki ti St. Peters and Paul to wa ni Kafin-koro, ijọba ibilẹ Paikoro, Rev Father Isaac Achi, sibẹ kayeefi nla niṣẹlẹ naa ṣi n jẹ fun ọpọ awọn to gbọ.
Awọn agbebọn la gbọ pe wọn yawọ ile ti olori ijọ naa, Father Achi n gbe ni nnkan bi aago mẹta oru oni, ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹẹdogun, oṣu kinni, ọdun 2023 ti a wa yii.
Yatọ si Father Achi ti wọn dana sun mọle, a gbọ pe wọn tun ṣe akẹgbẹ rẹ, Father Collins leṣe.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe b'awọn agbebọn naa ṣe yawọ ayika ile naa ni wọn ti gbiyanju lati wọle, ṣugbọn ti ko ṣee ṣe fun wọn. Eyi lo mu ki wọn ju ina sinu ile naa.
A gbọ pe niṣe ni wọn duro titi ti ile naa fi jona tan, pẹlu igbagbọ wi pe olori ijọ naa wa ninu ile.
Wọn ni ibi ti Father Collins ti salọ, ki ina ọhun ma ba a jo o, ni wọn ti dabọn bo o, to si jẹ pe ejika rẹ ni ibọn naa ba, eyi to jẹ ko ṣubu yakata, to si rapata yi sibi ti wọn ko ti ni rii pa.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Abiọdun Wasiu to f'idi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe igbesẹ ti n lọ lati rii pe ọwọ tẹ gbogbo awọn oniṣẹ ibi to lọwọ si iwa ọdaju naa, to si loun nigbagbọ pe ọwọ yoo tẹ wọn laipẹ.
Fọto ree...
No comments:
Post a Comment