Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti jẹ ko di mimọ pe awọọdun 'Gomina Ọdun 2022' toun gba lati ọdọ ileeṣẹ iwe iroyin Vanguard, kii ṣe fun oun, bi ko ṣe fun gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa.
Ọjọ Ẹti, Furaidee to kọja yii ni AbdulRazaq sorọ naa nibi to ti gba awọọdu gomina to ṣe daadaa lọdun 2022 to kọja lọ, eyi ti ileeṣẹ iwe iroyin Vanguard ṣagbekalẹ ẹ.
Eto ọhun lo waye ni gbọngan ile itura Eko, iyẹn Eko Hotel and Suites to wa lagbegbe Victoria Island, ipinlẹ Eko.
Lara awọn gomina to tun gba aami ẹyẹ yii ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Delta, Borno ati Akwa-Ibom.
Gomina ana nipinlẹ Ogun, Akinrọgun Oluṣẹgun Ọṣọba ati Gomina Obong Victor Attah lati ipinlẹ Akwa Ibom ni wọn pawọpọ gbe awọọdu ọhun fun AbdulRazaq.
Nibẹ lo ti sọ pe bi awọn ọmọ ipinlẹ oun ko ba fọwọsowọpọ, iṣẹ idagbasoke ko le rọrun f'oun lati ṣe, idi ree to fi loun fi sọri gbogbo awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa jakejado.
No comments:
Post a Comment