Hùn-ùn... Àwọn ohun tí ń da Nàìjíríà láàmú gan-an nìyí.
Ọlọ́run ń yan Olórí fún wa, gẹ́gẹ́ bí èrò, ìwà àti ìṣesí àwa fúnra wa.
Kò sí olórí kankan tó dáa lójú wa. Èmi ò gbàgbọ́ pé kò lè sí olórí tó dáa. Ìwà tí a bá ń hù sí wọn ńkọ́?
Bí Tinúbú bá ń sọ àléébù Àtíkù, tí Àtíkù náà ń sọ àléébù Tinúbú, Òṣèlú kan náà ni wọ́n. Ó yẹ kí àwa mẹ̀kúnnù ṣọ́ra láti máa dá sí i. Ohun tí ó kàn wá jù ni àdúrà àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Kí á ṣọ́ra fún ìwà ìdàlúrú, kí á yé bu ẹnu àtẹ́ lu olórí tí Ọlọ́run bá yàn fún wa. Kí a gba kádàrá, kí a sì máa bẹ Ọlọ́run Ọba lórí àṣeyọrí àti ìyípadà sí rere lórí olórí wa.
Ẹ jẹ́ kí ọkàn wa ó mọ́ sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọ́run bá yàn fún wa nínú oṣù tí ń bọ̀, kí a ṣe tán láti gbárùkù tì í lọ́dọ̀ àwọn alátakò rẹ̀.
Kò yẹ kí àwa ará ìlú tún máa dá kú ìṣòro Olórí wa, nígbà tí àwọn Òṣèlú alátakò rẹ̀ bá ń dà á láàmú.
...mo dákẹ́ díẹ̀ ná...
...mo sì fi ìyókù síkùn bí àwọn àgbààgbà...
Mo júbà oo
Ìbà Ọlọ́run Èdùmàrè
Ìbà Kábíèsí Ọlọ́tà Odò
Ìbà Ọkùnrin
Ìbà Obìnrin
Ìbà Ọmọdé
Ìbà ẹ̀yin àgbààgbà
Ẹ jẹ́ kó yẹ mí oo.
©
ÌȘỌ̀LÁ Sauban Àlàdé Orí-Àrán lèmi ń jẹ́
Ẹ̀ṣọ́ Ọmọ Ọlọ́tà Odò
👏🙇♂️👏
No comments:
Post a Comment