Awọn ohun ti ẹ ni lati mọ nipa Papa Ajasco to ku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 15, 2023

Awọn ohun ti ẹ ni lati mọ nipa Papa Ajasco to ku


Kii ṣe iroyin tuntun mọ wi pe Femi Ogunrombi, gbajugbaja oṣere adẹrinpoṣonu to n ko ipa Papa Ajasco ninu fiimu atigbadegba to jẹ ti Wale Adenuga ti jade laye.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ AWIKONKO ko tii le f'idi iru iku to pa ọkunrin naa mulẹ, ṣugbọn sibẹ, b'awọn kan ṣe n sọ pe Ogunrombi toju oorun de oju iku ni, bẹẹ lawọn kan n sọ pe aisan kekere kan lo kọlu ọkunrin naa to fi gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
 
Irọlẹ ana, Satide, Abamẹta ni iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Ogunrombi jade laye, paapaa gẹgẹ bi ọkan lara awọn agba oṣere tiata nni, Husseini Shaibu ṣe f'idi rẹ mulẹ loju opo Twitter rẹ laaarọ oni, ọjọ Aiku, Sannde.

Ohun ti AWIKONKO wa fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe Papa Ajasco meji lo wa lagboole Wale Adenuga Productions, ṣugbọn eyi to ku yii lo ṣẹṣẹ n ṣee bayii.

Abiọdun Ayọyinka lorukọ ẹni to n ko ipa Papa Ajasco naa tẹlẹ ninu ere atigbadegba to n dẹrin pẹẹkẹ awọn eeyan ni gbogbo igba.


Wọn ni iwe adehun to wa laaarin Wale Adenuga ati Ọgbẹni Ayọyinka fori ṣanpọn, lo fa a ti wọn fi lọ pe Ogunrombi lati wa maa tẹsiwaju ipa naa lọ.

Ọgbẹni Fẹmi Ogunrombi to jẹ agba nọọsi, iyẹn oṣiṣẹ eleto ilera lo jade laye, kii ṣe Ọgbẹni Abiọdun Ayọyinka lo jade laye o

Latigba ti iroyin ọhun ti jade ni ọpọ awọn iroyin ati iwe iroyin ori ayelujara ti n gbe fọto Ayọyinka jade wi pe oun lo jade laye, ti kii sii ṣe bẹẹ rara.

Eyi lo ja ki AWIKONKO wa fẹẹ fi to o yin leti wi pe kii ṣe Ayọyinka lo ku o, bi ko ṣe Ogunrombi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI