Gbajugbaja oṣere onigbagbọ nni, Mike Abayọmi Bamiloye ti sọ pe gbogbo awọn ti wọn n fi orukọ ewurẹ pe ni ko ni aaye kankan ti wọn yoo de si ni ọrun rere, nitori pe iwa wọn ni.
Mike Bamiloye to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ Mount Zion Film Production lo sọ eyi lori ikanni ayelujara ti Insitagiraamu rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, to si ni ko si ẹni ti wọn fi orukọ ewurẹ pe to le ri ọrun rere wọ.
O ni lotitọ, nnkan gidi ni ki wọn ṣapejuwe eeyan si nnkan rere, ṣugbọn ki wọn wa sọ iru ẹni bẹẹ si ewurẹ jẹ nnkan to buru jai.
Bamiloye sọ pe aṣa 'GOAT', iyẹn Greatest Of All Time ti awọn eeyan n da lakoko yii ku diẹ kaato, nitori pe awọn alagidi, ọlọkan lile ni wọn n pe bẹẹ.
‘GOAT’ ni apejuwe ti awọn ololufẹ ere idaraya fi n ṣapejuwe awọn dara julọ, paapaa laaarin Lionel Messi, agbabọọlu ilẹ Argentina ati akẹgbẹ rẹ, Cristiano Ronaldo, agbabọọlu ilẹ Portugal
Ninu ọrọ agba ojiṣẹ Ọlọrun naa, Bamiloye sọ pe orukọ Goat naa ninu bibeli tunmọ si alagidi, alaigbọran, olori kunkun ati ẹni ti wọn ko le nigbagbọ ninu ẹ, to si ni agutan tunmọ si ọmọ Ọlọrun.
“Ki ni itumọ GOAT? Eṣu lo tumọ itumọ rẹ fun un yin. GOAT tunmọ si alagidi, alainigbagbọ, alaironupiwada, olori kunkun ẹda.
“Awọn eeyan bi ewurẹ ko ni aaye kankan ni ijọba Ọlọrun. Gẹgẹ bi bibeli ṣe sọ, GOAT duro fun alaigbọran ati alainigbagbọ ẹda, nigba ti SHEEP [Aguntan] tunmọ si iwa bi Ọlọrun, Awọn onigbagbọ ọmọ Ọlọrun. Idi niyẹn ti Jesu fi sọ pe a maa ya awọn AGUNTAN kuro lara EWURE, a o si le gbogbo awọn alainigbagbọ ẹda sinu ina ayeraye.”
No comments:
Post a Comment