Gomina Abdurahman AbdulRazaq lonii, Ọjọbọ, Tọsidee ti bura fun Onidajọ Abiọdun Ayọdele Adebara gẹgẹ bii adele adajọ agba tuntun fun ipinlẹ Kwara
Igbesẹ yii la waye lẹyin ti adajọ agba ana, Onidajọ Suleiman Durosinlọrun Kawu fẹyinti lẹnu iṣẹ.
AbdulRazaq ni igbesẹ yii lo waye nitori boun ṣe bọwọ pupọ fun ofin, to si ni ipo adajọ agba naa ko gbọdọ ṣofo, idi to fi l'awọn ni idi pataki lati yan ẹlomiran dipo.
O ni yiyan ti wọn yan Onidajọ Adebara lo lọ nibamu pẹlu abala 271(4) ti iwe ofin orileede Naijiria, ti ọdun 1999.
No comments:
Post a Comment