Abẹokuta ni wọn ti ji iyaale ile gbe, Akurẹ ni wọn ti gburo rẹ bayii - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 12, 2023

Abẹokuta ni wọn ti ji iyaale ile gbe, Akurẹ ni wọn ti gburo rẹ bayii


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lati ri iyaale ile yii ti wọn sọ pe wọn ko tii ri latigba to ti kuro nile laarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, sibẹ a gbọ pe inu idaamu nla l'awọn mọlẹbi rẹ wa.
 
Fun awọn to ba ranti daadaa, a mu iroyin naa wa fun un yin wi pe agbegbe Gbọnagun, Odo Ẹran, Ọbantoko ni obinrin naa ti wọ ọkọ taisi, to si n lọ si ibi iṣẹ rẹ.
 
Ile ẹkọ alakọbẹrẹ ti F Kuti to wa lagbegbe Iṣabọ niluu Abẹokuta lobinrin naa, Arabinrin Olubukọnla Arikẹ Adebayọ ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọ.
 
Gẹgẹ bi ọkan lara awọn ara ṣọọṣi rẹ ṣe sọ laipẹ yii, o ni awọn ọlọpaa ti gburo rẹ nipa foonu to n lo siluu Akurẹ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko tii le sọ agbegbe to jẹ niluu Akurẹ.
 
Wọn ni obinrin naa lo fi atẹjiṣẹ ranṣẹ wi pe oun ṣẹṣẹ ji loju oorun ni, ati pe inu igbo nla kan loun pẹlu awọn eeyan rẹpẹtẹ kan wa, toun ko si le sọ pato ibi ti inu igbo naa wa.
 
Gbogbo akitiyan lati ba alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi sọrọ lori iṣẹlẹ naa lo ṣi n ja si pabo titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI