Gbogbo eto ni wọn lo ti fẹẹ pari bayii fun Aarẹ Muhammadu Buhari lati lewaju eto ipolongo idibo fun ipo aarẹ orileede Naijiria ati ti gomina, eyi to fẹẹ waye n'ipinlẹ Kwara.
Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kinni, ọdun ti a wa yii, iyẹn ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to n bọ la gbọ pe Buhari yoo fa ọwọ oludije s'ipo aarẹ lẹgbẹ naa, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ati oludije s'ipo gomina lẹgbẹ naa n'ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq soke lọjọ naa.
Ilu Ilọrin la gbọ pe ipolongo ita gbangba naa yoo ti waye, nibi ti gbogbo awọn oludije yoo ti maa sọ erongba wọn f'awọn araalu, ati idi ti wọn ṣe gbọdọ dibo fun wọn.
Lara awọn ti yoo tun wa nibẹ ni igbakeji Tinubu, Kaṣhim Ṣhẹttima, to fi mọ awọn igbimọ olupolongo idibo aarẹ, ti wọn yoo jọ kọwọrin papọ.
No comments:
Post a Comment