Gbajugbaja oṣere ori ayelujara nni, Debọ Adebayọ ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mista Makaroni ti parọwa fun gbogbo awọn ọmọ ati olugbe orileede Naijiria lati wo iru awọn oloṣelu ti wọn yoo dibo wọn fun lakoko eto idibo to n bọ lọna yii.
Oṣu keji, ọdun ti a wa yii ni eto idibo apapọ yoo waye lorileede Naijiria, nigba ti eto idibo gomina ati t'ipinlẹ yoo waye l'oṣu kẹta.
Mista Makaroni ninu ọrọ to kọ sori ikanni ayelujara rẹ sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe jẹ ki oloṣelu fun wọn lowo lati le dibo, nitori pe niṣe ni wọn fẹẹ fi owo ra ọjọ iwaju wọn.
O ni kii ṣe pe niṣe ni iru awọn oloṣelu to n ko owo silẹ lati ra ibo fẹẹ ṣe daadaa siluu, bi ko ṣe pe wọn wa dokoowo lasan ni, ti wọn si fẹẹ wa kowo jẹ.
“Oloṣelu to ba fun un yin lowo lati le dibo foun ko nii sin yin, tabi ṣe daadaa pẹlu yin. Wọn dokoowo lasan ni. Bi wọn ba de ori ipo, wọn maa kowo orileede yii to jẹ owo araalu jẹ ni.
“Ẹ ma ṣe dibo fun awọn ole ati awọn ọjẹlu.
“Ajẹnirun ni wọn.”
No comments:
Post a Comment