Alaṣẹ ati olori ijọ Living Faith, Biṣọọbu David Oyedepo ti yannayanna ẹni ti yoo jawe olubori ninu eto idibo Aarẹ to n bọ lọna ninu oṣu keji ọdun ti a wa yii.
Biṣọọbu Oyedepo sọ pe ẹni ti Ọlọrun nifẹẹ si ni yoo jawe olubori, ti ko si s'ohun tẹnikẹni le ṣe sii.
Oyedepo lo sọrọ naa nibi akanṣe eto adura fun orileede Naijiria, eyi to waye ninu ọgba fasiti Covenant.
Ninu ọrọ agba ojiṣẹ Ọlọrun naa, o ni
"Eto idibo orileede Naijiria to n bọ lọna yii yoo waye ni irọwọ-irọsẹ lai fa ogun lọ. Ko nii si itajẹ silẹ, wọn ko nii ta ẹjẹ ẹnikẹni kalẹ.
"Ifọkanbalẹ yoo wa, ati pe ondije ti Ọlọrun nifẹẹ si ni yoo di Aarẹ lati ṣakoso Naijiria.
"Naijiria yoo gbadun eto aabo gidi pada. Alaafia ati ifọkanbalẹ yoo wa lori ilẹ, okun, inu afẹfẹ ati nibi gbogbo."
No comments:
Post a Comment