Oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin agba orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party, PDP, Olumide Aderinokun ti sọ pe ẹnikan ṣoṣo to le mu orileede yii de ilẹ ileri ni Alaaji Atiku Abubakar, to si k'awọn araalu dibo fun un.
Aderinokun lo sọ eyi di mimọ nibi ipolongo idibo ti wọn ṣe nijọba ibilẹ Ọdẹda, ipinlẹ Ogun, to si ni ẹni to yẹ k'awọn ọmọ Naijiria nigbagbọ ninu ẹ lasiko yii ni Atiku.
Bakan naalo tun polongo fun oludije sipo gomina lẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Ọladipupọ Adebutu, to si ni ẹgbẹ PDP ni ifẹ araalu ju awọn to n ṣakoso lọwọ lọ.
O ni Adebutu ni ipinnu rere f'awọn araalu.
"Bii baba ni Alaaji Atiku Abubakar ṣe jẹ fun mi, nitori pe mo maa n gbadun ibaṣepọ emi pẹlu ẹ, to fi mọ awọn ọmọ ẹ.
"Mo le fọwọ sọya fun un yin pe Atiku ṣetan lati mu iṣọkan wọ Naijiria. Ọkan ṣoṣo la jẹ ni Naijiria, ki ẹnikẹni ma ro pe oun le pin wa sọtọọtọ nitori ohunkohun.
"A mọ, a si ni imọlara iya ti a n la kọja labẹ iṣakoso yii. PDP gẹgẹ bii mọlẹbi nipinlẹ Ogun, a ti ṣetan lati mu igbadun wa f'awọn eeyan nipa awọno agbekalẹ wa."
No comments:
Post a Comment