Beeyan ba wa nibi ti iya arugbo kan ti n gbadura fun gbajugbaja sọrọsọrọ agbaye nni, Kọlawọle Atanda Adejojo, yoo mọ pe adura rẹ n gba lojoojumọ.
Tọkan-tọkan ni mama naa to oni ipenija oju fi n gbadura fun Kasnaty, ẹni ti aye n gba tiẹ lasiko yii, nipa eto iranlọwọ to n ṣe f'awọn eeyan kaakiri.
Ọsẹ to kọja yii la gbọ pe Kasnaty lọ sagbegbe ti mama naa n gbe lati ṣaanu fun iya alakara kan nibẹ, akoko to wa nibẹ ni wọn ti ta a lolobo wi pe iya agba kan wa lagbegbe naa.
Bi Kasnaty ṣe debẹ ni mama yii ti bẹrẹ sii gbadura fun un.
Ṣugbọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ana, Mama yii gbadura tọkan-tọkan fun Kasnaty.
No comments:
Post a Comment