Idajọ ododo lo ti pada waye fun ọkunrin ọlọkada kan, Anietie Bassey Etim, ẹni to fipa ja ibale ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹtala ninu ṣọọṣi, ṣugbọn ti aṣiri rẹ pada tu.
Ẹwọn ogun ọdun ni ju Bassey, ẹni ọdun mẹrindinlogoji si laipẹ yii.
A gbọ pe niṣe ni Bassey, ọmọ bibi ilu Ikot Itie Udung to ewa nijọba ibilẹ Nsit Atai, ipinlẹ Akwa Ibom fi ọkada gbe ọmọ naa lọ si ṣọọṣi kan to da duro ninu igbo, to si f'ipa ba a laṣepọ karakara.
Nigba to n gbe idajọ ododo naa kalẹ, Onidajọ Gabriel Ette ti ile ẹjọ ogiga ipinlẹ Akwa Ibom ṣalaye pe Bassey, ẹni to yan iṣẹ ọkada gigun laayo jẹbi awọn ẹsun ifipabanilopọ ti wọn fi kan an.
Onidajọ Ette paṣẹ pe ẹwọn to kere ju si ẹsun ti wọn fi kan an naa ni ogun ọdun, to si ni ko lọ fi awọn akoko naa kẹkọọ
No comments:
Post a Comment