Wọn fi Kẹkẹ Maruwa ṣe ọmọ ọdun mọkanlelogun laanu, lo ba jiigbe salọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 30, 2022

Wọn fi Kẹkẹ Maruwa ṣe ọmọ ọdun mọkanlelogun laanu, lo ba jiigbe salọ


Bi gendekunrin, ọmọ ọdun mọkanlelogun ti ẹ n wo yii, Muhammed Umar ba fi bọ ninu iwa oju-kokoro ati afọwọfa to kọ ara rẹ si yii, a jẹ pe ori lo ko o yọ.
 
Umar la gbọ pe wọn gbe Kẹkẹ Maruwa fun lati sare fi ṣiṣẹ, bo ba ṣe fi n ṣiṣẹ, ti wọn si ni ko pẹ ti wọn gbe e fun un to si gbe e na papa bora.
 
Agbegbe ti wọn pe ni Bayan Tike, Kasuwan Kuturu niluu Mubi, ipinlẹ Adamawa ni wọn sọ pe Umar n gbe.
 
Nigba to n f'idi iṣẹlẹ naa to akọroyin leti, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Suleiman Nguroje sọ pe ọrẹ Umar kan lo fi Kẹkẹ Maruwa naa ṣee laanu lagbegbe Mubi.
 
Nguroje sọ pe agbegbe Mararaba Mubi lọwọ ti tẹ Umar. O ni ṣe ni Umar sọ fun obinrin kan sọ pe koun gbe e lọ si agbegbe kan ni Mubi, to si loun yoo san ẹgbẹrun meji naira f'oun.
 
O ni ọgbọn iṣẹju pere ni Umar tọrọ lati fi lo Kẹkẹ Maruwa naa, ko le fi ri owo ounjẹ, ati pe oun yoo da ẹgbẹrun kan aabọ naira pada, lẹyin toun ba fi ṣiṣẹ tan.
 
Bo ṣe gba Kẹkẹ naa tan, lo ba na papa bora, ti wọn ko si rii.
 
Nguroje sọ pe ọwọ ti tẹ Umar, o si ti di dandan wi pe ko f'oju ba ile-ẹjọ.
 
Ju gbogbo rẹ lọ, Umar nigba to n bẹbẹ sọ pe iṣẹ ati oṣi to n ba oun finra lo fa a toun fi gbe igbesẹ naa, lai mọ pe aṣiri yoo pada tu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI