Opurọ aye ati ọrun ni Atiku, ẹ ma ṣe dibo fun ooo - Tinubu pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, December 12, 2022

Opurọ aye ati ọrun ni Atiku, ẹ ma ṣe dibo fun ooo - Tinubu pariwo sita


Oludije s'ipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Tinubu ti ṣapejuwe oludije s'ipo naa labẹ ẹgb
ẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar gẹgẹ bi opurọ nla.
 
Tinubu sọ pe ọdun 2023 ni opin Atiku nidii oṣelu, paapaa nipa gbigbe apoti ipo Aarẹ Naijiria, ati pe irọ nla ati ayederu iroyin lo n gbe kaakiri.
 
O gba awọn ọmọ Naijiria lati ma ṣe gba awọn ileri ti Atiku n ṣe kaakiri gbọ, nitori pe ẹtanjẹ lasan ni gbogbo ileri naa, ko si otitọ kankan nibẹ.
 
Tinubu lo sọrọ naa l'ọjọ Aiku, Sannde to kọja nipasẹ alakoso eto ipolongo rẹ, Bayọ Ọnanuga.
 
O ni ọrọ ti Atiku sọ nibi ipolongo to lọ ṣe niluu Abuja laipẹ yii nipa wi pe ko si eto aabo nidi okoowo ati iṣẹ agbẹ, irọ to jinna si otitọ ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI