Ileeṣẹ ọlọpaa orileede yii ti sọ pe k'awọn araalu lọ fọkan wọn balẹ bi wọn ba ji mọto wọn gbe, nitori pe awọn ti gbe ọna abayọ lati tete ri awọn mọto ti wọn ba jigbe gba pada.
Ọga ọlọpaa ni Naijiria, Usman Alkali Baba ti kede wi pe awọn ti gbe ikanni t'awọn araalu yoo ti maa fi to ileeṣẹ wọn leti nipa awọn ọkọ ti wọn ba jigbe ati agbegbe ti wọn ti ji wọn gbe.
Ninu atẹjade ti alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi fi sita lo ti sọ pe wọn ti gbe ileeṣẹ naa ti wọn pe ni Central Motor Registry (CMR) lori ẹrọ ayelujara, eyi to ni olu-ileeṣẹ wa niluu Abuja.
O ni ọga agba wọn bu ọwọ lu eto yii lati mu ẹdinku ba wahala ti wọn n ṣe nipa eto igbofinro, iṣẹ iwadii ati ifẹsunkan nile ẹjọ lọna igbalode.
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo awọn mọto ti wọn ba ti jigbe lati ọjọ kinni, oṣu kinni, ọdun 2018, titi di asiko yii, ti wọn ko si tii ri gba pada ni anfaani wa fun, pẹlu idaniloju pe iṣẹ yooo bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lori ẹ.
Adejọbi ni yatọ olu ileeṣẹ wọn meji to wa niluu Abuja ati Eko, awọn tun ni ẹka ileeṣẹ wọn ti ko di ni mẹtadinlogoji kaakiri orileede Naijiria, pẹlu awọn ọkọ ti wọn fi n ṣiṣẹ, eyi ti ko di ni igba.
O wa gba awọn ọmọ Naijiria ti wọn ba ti ji mọto wọn gbe lamọran lati lọ sori itakun naa https://reportcmr.npf.gov.ng, ki wọn si kọ gbogbo awọn ohun idanimọ ọkọ naa sibẹ lati bẹrẹ lori ẹ, bẹrẹ lati ọjọ keje, oṣu kejila ti a wa yii.
No comments:
Post a Comment