Ojoojumọ ni mo n gbadura ki igbeyawo mi ma ṣe daru - Toyin Abraham - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, December 30, 2022

Ojoojumọ ni mo n gbadura ki igbeyawo mi ma ṣe daru - Toyin Abraham


Gbajagbaja oṣerebinrin nni, Toyin Abraham ti sọ ọ sita gbangba wi pe ko si ohun meji to n ba oun lẹru nile aye lakoko yii, bi ko ṣe pe ile to daru, to si ni ojoojumọ loun n gbadura wi pe ki ile oun ma ṣe daru.
 
Toyin Abraham lo sọrọ naa nibi ifọrọwerọ kan to ṣe laipẹ yii pẹlu ileeṣẹ Media Room Hub, to si loun ati ọkọ oun l'awọn jọ n gbadura naa lojoojumọ.
 
O loun ko la muu mọra wi pe koun ati ọkọ oun maa gbe lọtọọtọ, ati pe oun ko tun dẹkun lati maa gbadura lodi si ọkunrin ati obinrin ajoji to n da idile ru.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Mi o tiẹ fẹẹ padanu igbeyawo mi. Mi o tiẹ fẹẹ ki igbeyawo mi fi ọjọ kan daru. Mi o le maa wo ara mi ati ọkọ mi lati maa gbe lọtọọtọ, ko le ṣẹlẹ, nitori pe mi o le muu mọra.

“Mo mọ pe ọkọ mi ko le fi mi silẹ, bẹẹ ni emi naa ko le fi ọkọ mi silẹ, ṣugbọn ohun kan ṣoṣo ti mo n bẹru niyẹn. Idi ree ti a fi jọ maa n gbadura papọ lodi di ọkunrin ati obinrin ajoji to maa n da idile ru. Ohun kan ṣoṣo to n ba mi lẹru niyẹn, ṣugbọn mo mọ pe Ọlọrun lo yan an, ko si si nnkan to too bẹru nibẹ.”
 
Bẹ o ba gbagbe, ọdun 2013 ni Toyin, iyẹn Mama Ire ṣe igbeyawo pẹlu Johnson Adeniyi, ṣugbọn ti igbeyawo naa daru lọdun 2015. Ọdun 2019 lo ṣe igbeyawo miran pẹlu Kọlawọle Ajeyẹmi, to pada bimọ fun bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI