Owọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ gendekunrin, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Moses Ayọmide ti wọn lo ṣeku pa ọmọkunrin kan ti wọn pe ni Qudus Popoọla.
Agbegbe Agbado to wa n'ijọba ibilẹ Ifọ, ipinlẹ Ogun la gbọ pe ọwọ ti tẹ Ayọmide, ẹni ti wọn sọ pe ogbologbo adigunjale to tun n ṣe ẹgbẹ okunkun ni.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn lawọn ara agbegbe naa ni wọn ranṣẹ pe awon ọlọpaa wi pe awọn adigunjale n ṣọṣẹ lọwọ ladugbo Fadahunsi to wa ni Agbado.
Loju ẹsẹ ni ọga ọlọpaa Agbado ti gbera pẹlu ikọ r lati lọ koju wọn.
Loju ẹsẹ ni ọga ọlọpaa Agbado ti gbera pẹlu ikọ r lati lọ koju wọn.
Abimbọla Oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba to n gbe iroyin naa si wa leti ṣalaye pe ṣaaju k'awọn ọlọpaa too debẹ, Ayọmide ti yinbọn pa Qudus, ẹni ọdun marundinlọgbọn.
Oyeyẹmi tẹsiwaju pe ẹni kan to n fi owo dokoowo, iyẹn POS, Basirat Anibire ni Ayọmide lọ fi ibọn ja lole, asiko ti awọn ara adugbo si n le e lo yinbọn ba Qudus, tiyẹn si gbabẹ ku loju ẹsẹ.
O ni bi wọn ṣe yọ si Basirat, ni wọn ti fa ọmọ rẹ, ọmọ ọdun meje mọra, pẹlu erongba lati pa ọmọ naa bi ko ba fun wọn loun ti wọn n fẹ, ti wọn si l'obinrin naa rawọ ẹbẹ pe ki wọn ma ṣe pa ọmọ oun, asiko naa ni wọn raaye ja baagi rẹ ti owo wa nibẹ gba.
Agbẹnusọ naa lo jẹ ka mọ pe ẹgbẹrun lọna irinwo naira, pẹlu foonu Itel ni Ayọmide f'ibọn gba lọwọ Basirat, ko to na papa bora. Nibi to si tun ti n salọ lo ti ṣe Falyẹyẹ Oluwaṣeun.
Siwaju sii lo sọ pe awọn ọdọ adugbo naa lo ṣe iranwọ bọwọ ṣe tẹ Ayọmide lakoko to n salọ. A tiẹ gbọ pe kii ṣe Ayọmide nikan lo lọ digunjale naa, wọn loun atawọn ọrẹ rẹ t'awọn ti juba ehoro ni, ṣugbọn oun nikan lọwọ tẹ.
Oyeyẹmi tun fi kun ọrọ rẹ pe bo tilẹ jẹ pe awọn mọlẹbi Qudus ti gba oku rẹ, wi pe awọn yoo lọ sin in nilana musulumi, sibẹ, o ni ẹnikan yooku toun farapa ti wa l'ọsibitu to ti n gba itọju.
Bakan naa lo ni alupupu, iyẹn Okada ti ko ni ina lori l'awọn adigunjale mẹta naa gbe wa jale wọn ni nnkan bi aago meje alẹ ti Basirat fẹẹ tilẹkun.
Igbe ati ariwo rẹ lo mu k'awọn ara adugbo naa sare dide, ti wọn si le awọn adigunjale yii, ko to di pe wọn ranṣẹ s'awọn ọlọpaa.
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn lọ ṣe iwadii nipa Ayọmide daadaa, ki wọn si wa ọna b'ọwọ yoo ṣe tẹ awọn yooku rẹ, ko to di pe wọn f'oju rẹ ba ile-ẹjọ.
No comments:
Post a Comment