Ọgba ẹwọn ni Babangida Buhari, atawọn ajinigbe yii ti n ṣọdun Keresimesi lọwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 25, 2022

Ọgba ẹwọn ni Babangida Buhari, atawọn ajinigbe yii ti n ṣọdun Keresimesi lọwọ


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn mẹwaa kan ti wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ ajinigbe lọ, ti a si gbọ pe ọpọ awọn eeyan ni wọn ti jigbe l'awọn opopona kaakiri ilẹ Yoruba.
 
Awọn eeyan yii la gbọ pe wọn n ji awọn eeyan gbe lopopona Eko si Ibadan.
 
Bẹ o ba gbagbe, opopona Eko si Ibadan naa lawọn ajinigbe yii ti ji igbakeji Giwa fasiti ilu Ibadan, Ọjọgbọn Adigun Agbaje gbe lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

Aṣọ ologun la gbọ pe awọn ajinigbe naa wọ lọjọ ti wọon ji Ọjọgbọn Agbaje gbe.
 
Nigba to n f'oju awọn ọdaran naa han ninu ọgba ileeṣẹ ọlọpaa to wa lagbegbe Ẹlẹyẹle niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ l'Ọjọbọ, Tọsidee to kọja, ọga ọlọpaa ipinlẹ naa Adewale Ọṣifẹsọ, o ni ọwọ tẹ awọn ọdaran naa lẹnu iṣẹ buruku wọn.
 
Ọṣifẹsọ sọ pe awọn ọdaran yii lo kọlu ikọ ọlọpaa ti wọn lọ lati gba awọn ti wọn jigbe silẹ ninu igbo kijikiji, nibi ti wọn ti pa ọlọpaa kan, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ gbogbo wọn.
 
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe nipa iranlọwọ awọn ẹṣọ aabo Amọtẹkun, ẹka tipinlẹ naa ni wọn fi ri awọn mẹwẹẹwa mu, ti wọn si ri awọn ti wọn jigbe gba pada lai farapa.
 
Ọga ọlọpaa sọ pe Babangida Buhari Awalu ati Kabiru Aliyu ni olori wọn, ti wọn si wa lara awọn tọwọ tẹ.
 
A gbọ pe iṣẹ ọkada gigun ni pupọ awọn tọwọ tẹ naa n ṣe niluu Ibadan, ati pe ibi ti wọn ti n gba owo ijinigbe lọwọ awọn akẹgbẹ wọn lọwọ ti tẹ wọn lagbegbe Ọjọọ niluu Ibadan.
 
Awọn mẹta ti ọwọ tẹ gbẹyin ninu wọn ni Adewuyi Sunday, Ayanwọla Gbenga ati Rafiu Abdulmajeed ti wọn wa lati agbegbe Gbugbu nipinlẹ Kwara ati Agọ-Are nipinlẹ Ọyọ.
 
Ọṣifẹsọ ni miliọnu meje aabo anira, ibọn AK-47 mẹrin ọtọọtọ pẹlu ọta ibọn marundinlọgọrin, to fi mọ aṣọ ologun ati fila ọlọpaa ni wọn gba lọwọ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI