Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun labẹ ọga agba Sikirulai Ọlanrewaju Bankọle ti sọ pe ikoko ko nii gba omi, ko tun gba ẹyin laaarin ohun ati awọn tọọgi to n ba patako ipolongo oṣelu jẹ kaakiri ipinlẹ naa.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe jade laarọ oni, Ọjọru, Wẹsidee, eyi ti alukoro wọn, Abimbọla Oyeyẹmi fi ranṣẹ s'AWIKONKO, o ni eyi t'awọn gboju fo iwa buruku naa da ti to, nitori pe igbesẹ ofin ti bẹrẹ.
"Ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣe agbeyẹwo daadaa, pẹlu kikọminu si bi awọn tọọgi ṣe n ba patako ipolongo oṣelu jẹ kaakiri ipinlẹ yii. L'ọsẹ to kọja, awọn tọọgi kan lọọ ba patako ipolongo ẹgbẹ oṣelu APC jẹ, laipẹ yii naa, awọno tọọgi miran tun lọ ba patako ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP jẹ.
Fun idi eyi, ileeṣẹ ọlọpaa fẹẹ gba gbogbo awọn to wa nidii iwa ibajẹ yii lamọran lati jawọ kuro nibẹ, tabi ki wọn gba wi pe awọn ti ṣetan lati f'oju winna ofin iwa ti wọn hu."
Ileeṣẹ ọlọpaa jẹ ko di mimọ pe awọn ko nii gba iwa aibofin mu naa mọ ṣaaju, lọjọ ati lẹyin eto idibo apapọ ọdun 2023 to n bọ lọna yii.
"Ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ ni yoo jẹ iyan rẹ n'iṣu ni ibamu pẹlu ofin orileede yii."
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa tun gba gbogbo araalu lamọran lati tete maa fi to wọn leti, bi wọn ba kofiri ẹnikẹni to n ba patako ipolonbo oṣelu jẹ, nitori pe ẹni tọwọ ba tẹ yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ, ti yoo si kabamọ iwa to hu.
O ni gbogbo eto lawọn n ṣe lati rii pe wọn dẹkun awọn iwa ti yoo da wahala oṣelu silẹ, bi eto idibo ṣe n sunmọ etile.
No comments:
Post a Comment