O pari! Ajinigbe meji ti ha l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 14, 2022

O pari! Ajinigbe meji ti ha l'Ogun



Ọwọ ileeṣẹ eleto aabo n'ipinlẹ Ogun, iyẹn So-Safe Corps ti tẹ awọn meji kan ti wọn sọ pe wọn ko ni iṣẹ meji, to kọja ijinigbe kaakiri ipinlẹ naa ati agbegbe rẹ.
 
Gẹgẹ bi Mọruf Yusuf to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ So-Safe Corps ṣe ṣalaye f'AWIKONKO, o ni nnkan bi aago mẹta aabọ ọsan, Ọjọru, Wẹsidee oni, lọwọ tẹ awọn ajinigbe meji naa.
 
Bẹẹ lo tun jẹ ko di mimọ pe awọn ti gba ẹni ti wọn jigbe silẹ lọwọ wọn, lakooko ti wọn fẹẹ gba owo lori ẹni naa lọwọ awọn eeyan rẹ.

Yusuf sọ pe mẹfa ni awọn ajinigbe naa jẹ, ṣugbọn to ni meji pere lọwọ palaba wọn segi, ati pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati rọwọ to awọn yooku.

Ninu atẹjade ti Yusuf fi sita, o ni ọkunrin to pe orukọ ara rẹ ni Ṣeyi Olorunṣogo ni wọn jigbe niwaju ile rẹ ladugbo Solu, Rounder niluu Abẹokuta.

O ni iyawo Ṣeyi ni wọn kọkọ jigbe, ko to di pe ọkunrin naa dọbalẹ wi pe ki wọn fi iyawo oun silẹ, ki wọn si maa gbe oun lọ, ti wọn si gba sii lẹnu.

Latibẹ la gbọ pe wọn ti mu ọkunrin naa wọnu igbo lọ. Agbegbe Onigbẹdu, Ewekoro to wa n'ijọba ibilẹ Ifọ ni wọn gba salọ.
 
Nibi ti wọn ti n lọ ni iroyin ọhun tun fi to wa leti pe bi wọn ṣe agbegbe Onigbẹdu ni wọn pade Francis Oke ninu oko rẹ to ti n ṣiṣẹ agbẹ, ti wọn si tun ji oun naa gbe, ṣugbọn toun pada salọ mọ wọn lọwọ, nitori bo ṣe mọ gbogbo agbegbe ọhun daadaa.

Yusuf ṣalaye pe Francis to salọ mọ wọn lọwọ lo pada lọ ta awọn oṣiṣẹ wọn to wa nitosi lolobo, ko to di pe iṣẹ iwadii bẹrẹ.

 
 
Nibi ti wọn ti n wa awọn ajinigbe naa ninu igbo, la gbọ pe wọn ti yinbọn fun ọkan lara wọn, ti wọn si sare lọ tọju ẹ. Lẹyin ẹ ni wọn pada ri meji ninu awọn ajinigbe naa mu.

Yusuf darukọ awọn meji tọwọ tẹ naa gẹgẹ bii Umọru, ọmọ bibi ipinlẹ Kwara ati Alliu toun wa lati ipinlẹ Kẹbbi.
 
Lara awọn nnkan to lawọn ri gba lọwọ wọn ni ibọn kan.
 
O wa jẹ ko ye wa pe ọga awọn, Sọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn lọ fa awọn ajinigbe naa le awọn ọlọpaa ẹkun Ewekoro lọwọ fun iṣẹ iwadii kikun.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI