Omijẹ kikoro lo gba ẹnu awọn eeyan lopopona Ṣagamu si Benin lonii, Ọjọru, Wẹsidee nigba ti obinrin meje ọtọọtọ padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ to waye.
AWIKONKO gbọ pe niṣe mọto ti awọn eeyan naa jona di eeru, ti ko si s'ẹni to le da ẹnikankan mọ ninu awọn to padanu ẹmi wọn naa.
Gẹgẹ bi alakoso eto irinna ẹkun Ijẹbu Ode, Ọṣinbajo F ṣe ṣalaye, o ni motọ bọọsi Mazda ti nọmba idanimọ rẹ jẹ AGL 886 YD lo jona gburugburu.
Ọṣinbajo lo jẹ ka mọ pe obinrin mẹrinla ati ọkunrin kan toun jẹ awakọ lo wa ninu mọto bọọsi naa lakoko ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
A gbọ pe niṣe ni bọọsi naa gbona lori ere, to si ṣe bẹẹ gbina ki oloju too ṣẹ ẹ. Omi ni wọn sọ pe o gbẹ mọ inu mọto ọhun, eyi to pada fa ijamba buruku yii.
Wọn ni niṣe l'awọn meje jona kọja idanimọ nigba ti mọto naa jona, ti awọn yooku si farapa yannayanna.
Awọn ẹṣọ aabo oju popona ti FRSC ati TRACE la gbọ pe wọn sare de ibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si doola ẹmi awọn eeyan. Awọn ẹṣọ aabo naa ni wọn tun ko awọn to farapa lọ si ọsibitu lati gba itọju.
No comments:
Post a Comment