Iroyin to ba ni lọkan jẹ pupọ lo waye lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii, nigba ti wọn sọ pe tanka elepo kan jọna di eeru, ti eeyan kan naa si kagbako ijamba ina ọhun.
Nnkna bi aago mẹwaa aabọ aarọ la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye lopopona marosẹ Ṣagamu siluu Ijẹbu Ode.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ aabo oju popona t'ijọba apapọ, iyẹn Federal Road Safety Corps (FRSC), Florence Okpe ṣe ṣalaye, o ni orin irin ni tanka epo naa ti jona.
Okpe ni awọn meji lo wa ninu tanka epo ọhun lakoko to jona, ọkunrin meji si ni wọn. O lẹni kan lo farapa, ti ẹnikan yooku si jona di eeru.
Bẹẹ lo jẹ pe ko ye wa pe awọn ti gbe ẹni to farapa lọ si ọsibitu to ti n gba itọju lọwọ, ti eyi to jona ku si ti wa ni mọṣuari.
No comments:
Post a Comment