Ọrẹ mẹta kan ni wọn ti foju ba ile-ẹjọ majisireeti to wa niluu Ado-Ekiti, ipinlẹ Ekiti lonii, Ọjọru, Wẹsidee lori ẹsun wi pe wọn ji ewurẹ gbe.
Bamiṣaye Felix, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn; Adebayọ Wasiu, ẹni ọdun marundinlogoji ati Kọlawọle Sunday, toun jẹ ẹni ọdun mejilelogoji lawọn mẹtẹẹta tọwọ tẹ.
Nigba to n fẹsun kan wọn niwaju ile-ẹjọ, Bamikọle Ọlasunkanmi to jẹ agbefọba sọ pe nnkan bi aago mẹrin aarọ kutu ọjọ kẹrin, oṣu kejila, ọdun ti a wa yii lọwọ tẹ wọn nibi ti wọn ti lọ ji ewurẹ gbe.
Agbegbe kan ti wọn pe ni Iye-Ekiti ni iroyin fi to wa leti pe awọn mẹtẹẹta ti lọ ji ewurẹ naa ti iye owo rẹ to ẹgbẹrun marundinlogoji to jẹ ti Oyeyẹmi Funmilayọ.
Ni kete ti wọn lọ fa awọn mẹtẹẹta yii le awọn ọlọpaa lọwọ la gbọ pe wọn ti bẹrẹ iwadii lori wọn, ti wọn si pada ri ewurẹ marun ọtọọtọ ati aguntan kan lọwọ wọn, eyi ti igbagbọ wa wi pe wọn ji wọn gbe ni.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn yii lo tako iwe ofin ọdaran ti ipinlẹ Ekiti tọdun 2021, ti abala 302(1) (a) ati 345.
Ọlasunkanmi wa rọ ile ẹjọ lati sun igbẹjọ siwaju, ki wọn le tubọ ko gbogbo awọn ẹri ati olujẹri wa sile ẹjọ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn mẹtẹẹta sọ pe awọn ko jẹbi pẹlu alaye, sibẹ, agbẹjọro awọn mẹtẹẹta, Arabinrin Aduni Ọlanipẹkun rọ ile-ẹjọ lati faaye beeli silẹ fun wọn.
Onidajọ Saka Afunsọ wa gbe ẹbẹ naa, to si ni ki awọn mẹtẹẹta san ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ bi owo beeli, pẹlu oniduro kọọkan. Bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹsan, oṣu kinni, ọdun 2023.
No comments:
Post a Comment