Aarẹ Muhammadu Buhari ti dagbere f'awọn ọmọ Naijiria wi pe oun n ti lọ si orileede Amẹrika, to si loun ko ni pẹẹ de pada.
Ibi ipade awọn olori ilẹ Amẹrika ati Afrika, eyi to fẹẹ waye niluu Washington DC ni Aarẹ Buhari kede wi pe oun n lọ.
Ọsan ana, tii ṣe Aiku, Sannde ni Aarẹ Buhari lọ wọ ọkọ baluu lati ipinlẹ Katsina, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ.
Ọjọ kẹtala ati ọjọ karundinlogun, oṣu kejila, ọdun ti a wa yii ni ipade naa feẹ waye, eyi ti Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden fẹẹ fi wa oju awọn adari ilẹ Afrika.
A gbọ pe Aarẹ Biden fẹẹ fi ipade naa jẹ ki ibaṣepọ to wa laaarin ilẹ Amẹrika ati Afrika tubọ maa tẹsiwaju, ko si tun gbooro sii.
No comments:
Post a Comment