Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ti f'idi rẹ mulẹ pe awọn ajinigbe ti tu ọba alaye kan, Ọba Clement Jimoh Olukọtun silẹ lahamọ wọn, lẹyin ti wọn gba miliọnu mẹwaa naira.
Ọba Olukọtun, Oṣo tiluu Ajọwa to wa nijọba ibilẹ Akoko North-West, ipinlẹ Ondo ni wọn jigbe ni nnkan bi ọjọ mẹjọ sẹyin.
AWIKONKO gbọ pe nnkan bi aago mẹwaa alẹ, Ọjọru, Wẹsidee to kọja ni wọn tu kabiyesi naa silẹ, ti wọn si lọ wa a ju si agbegbe kan n'ipinlẹ Kogi.
Ọba ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin naa la gbọ pe owo ti ko din ni miliọnu mẹwaa naira lawọn ẹbi rẹ gbe kalẹ fawọn ajinigbe naa.
Ọjọbọ, Tọsidee la gbọ pe awọn ajinigbe yii yawọ aafin ọba naa, ti wọn si jiigbe salọ.
Lẹyin naa ni wọn n beere fun ọgọrun-un miliọnu naira ki wọn too tu silẹ, ṣugbọn ti wọn pada gba miliọnu mẹwaa naira lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ.
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ọsibitu kan la gbọ pe Kabiyesi naa wa niluu Lọkọja, nibi to ti n gba itọju lọwọ.
No comments:
Post a Comment