Kwara2023: Ẹ jawọ ninu biba patako ipolongo jẹ o - APC ṣe ikilọ nla fun PDP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 7, 2022

Kwara2023: Ẹ jawọ ninu biba patako ipolongo jẹ o - APC ṣe ikilọ nla fun PDP


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC nipinlẹ Kwara ti ṣe ikilọ fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ naa lati dẹkun nipa biba patako ipolongo, Billboard to jẹ t'awọn oludije lẹgbẹ APC jẹ.
 
Wọn ni gbigba alaafia ati iṣọkan laaye ni yoo jẹ ki ipinlẹ naa tẹsiwaju, ati pe ki wọn yago fun oṣelu ẹtaanu ti wọn gunle.
 
Lọjọ Aje, Mọnde to kọja yii ni ẹgbẹ APC gbe ikilọ naa sita ninu atẹjade ti wọn fi sita, latari bi awọn oludije ṣe n kọminu b'awọn tọọgi ṣe n ba patako ipolongo wọn jẹ.
 
Ninu atẹjade naa ni wọn ti jẹ ko ye ẹgbẹ oṣelu PDP wi pe iwa ti wọn n hu nipa biba awọn patako ipolongo awọn oludibo wọn jẹ le da wahala tabi ija oṣelu silẹ lawujọ, ti wọn si gbọdọ jawọ.
 
Wọn ni iwa ti ẹgbẹ alatako naa n hu lasiko eto oṣelu yii yoo jẹ ipalara fun ipinlẹ Kwara lati yan awọn adari ti ko nifẹẹ wọn, ki wọn si faaye silẹ fawọn araalu lati yan ẹni ti wọn n fẹ.
 
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ wi pe o n ba patako ipolongo oludije labẹ APC jẹ yoo fẹnu f
era bi abẹbẹ labẹ ofin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI