Gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata kaakiri ipinlẹ Kwara lonii, Ọjọbọ, Tọsidee ni wọn fi ontẹ lu gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq lati dibo fun un lẹẹkeji, ti wọn si ni asọrọṣẹ to ti mu ọpọ ileri ṣẹ ni.
Wọn ni igbayegbadun awọn oṣiṣẹ jẹ gomina Kwara logun, eyi ti wọn sọ pe ko ṣẹlẹ ri ninu itan ipinlẹ naa, nitori pe Gomina AbdulRazaq n ṣe ẹtọ to ba yẹ fun wọn.
Gbọngan Banquet to wa niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ni awọn oṣiṣẹ ti sọrọ idaniloju naa jade, nibi akanṣe eto ti wọn fi n saami ayẹyẹ ọsẹ awọn oṣiṣẹ ijọba tọdun 2022, iyẹn 2022
Civil Service Week.
Eto ọhun ti ileeṣẹ olori awọn oṣiṣẹ n'ipinlẹ naa, Arabinrin Susan Modupẹ Oluwọle ṣagbatẹru ẹ, ni wọn ti gba alejo Gomina AbdulRazaq, ẹni ti igbakeji rẹ, Kayọde Alabi ṣojuu fun; awọn oloṣelu; awọn alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ ti NLC, Kọmnureedi
Issa Ọrẹ; TUC, Kọmureedi Tunde Joseph; Joint Negotiating
Council, Kọmureedi Saliu Suleiman; atawọn miran.
Nibẹ ni wọn ti sọ pe gomina wọn yii lo jẹ ki wọn bẹrẹ sii ni imọlara eto oṣelu awaarawa, nipa awọn eto ọlọkan-o-jọkan tijọba n gbe kalẹ, eyi to n tun igbe aye wọon ṣe.
Igbakeji gomina, Kayọde Alabi nigba toun naa n sọrọ jẹ ko di mimọ pe igbe aye irọrun lo jẹ oun logun f'awọn oṣiṣẹ, eyi to mu ki wọn maa san owo oṣu wọn deedee, ati fi fun wọn ni igbega to tọ si wọn lasiko.
Bakan lo jẹ ko di mimọ pe oun ko ni erongba lati da oṣiṣẹ kankan duro nigba toun ba wọle ẹlẹẹkeji, nitori pe lara awọn ohun to n mu ilọsiwaju ba ilu ni wiwa iṣẹ ti yoo gbe ounjẹ sori tabili awọn eeyan.
O ni dida oṣiṣẹ duro kọ ni ọna abayọ, nitori pe irinṣẹ to ṣe pataki ni awọn oṣiṣẹ jẹ ninu eto idagbasoke ilu.
No comments:
Post a Comment