Bi gbogbo awọn Kristẹẹni ṣe n ṣajọyọ ọjọ ibi Jesu Kristi kaakiri agbaye, ti wọn si n ki ara wọn ku oriire, naa ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ba gbogbo wọn yọ patapata.
Gomina AbdulRazaq ṣapejuwe ayẹyẹ ọlọdọọdun naa gẹgẹ bi eyi to ṣara-ọtọ lati yọ ninu ẹ, ati lati ṣe amulo aanu Ọlọrun ati ọjọ ibi Jesu Kristi.
Ninu lẹta ikini ti gomina fi ranṣẹ s'awọn ọmọlẹyin Jesu, o dupẹ lọwọ wọn fun ifẹ ti wọn ni si iṣakoso oun, ati bi wọn ṣe jẹ ọkan pataki lara awọn alafọwọsowọpọ ninu iṣakoso oun, eyi to n mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba ipinlẹ Kwara ni gbogbo igba.
No comments:
Post a Comment