Ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si Ogun State Community, Social Orientation and Safety Corps, iyẹn So-Safe Corps ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori awọn adigunjale ti wọon na papa bora l'ọsẹ to kọja yii n'ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta, ipinlẹ naa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ So-Safe Corps, Mọruf Yusuf lo sọ eyi di mimọ laipẹ yii lakoko to n ṣalaye pe awọn ri awọn dukia t'awọn adigunjale jigbe gba pada lọwọ wọn lakoko ti wọn n na papa bora.
Yusuf ni l'ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu to kọja lawọn lọ koju awọn adigunjale kan ti wọn lọ digunjale laipẹ yii, iyẹn ni nnkan bi aago mẹrin irọlẹ.
O ni agbegbe Gasline to wa ni Arobiẹyẹ, ijọba ibilẹ Ọta ni wọn ti kofiri awọn adigunjale naa lakoko ti wọn n bọ lati oko ole wọn, to si lawọn koju wọn.
Lara awọn dukia to lawọn ri gba ni ọkada Bajaj tuntun ti nọmba idanimọ rẹ jẹ TRE 231 VT; ibọn agbelẹrọ kan, bata, ohun mimu ẹlẹrindodo 5Alive; aṣọ; oogun abẹnugọngọ ati bẹẹbẹẹlọ.
Yusuf jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn ẹru naa lawọn ti ko lọ sọdọ awọn ọlọpaa ẹkun Onipanu fun iwadii siwaju sii.
Diẹ ree lara awọn ẹru naa:
No comments:
Post a Comment