Iṣẹ rẹpẹtẹ de f'awọn araalu: Ẹ wo aragbayamuyamu ileeṣẹ aṣọ t'ijọba Kwara ṣẹṣẹ pari - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, December 4, 2022

Iṣẹ rẹpẹtẹ de f'awọn araalu: Ẹ wo aragbayamuyamu ileeṣẹ aṣọ t'ijọba Kwara ṣẹṣẹ pari


Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, inu idunnu ati ayọ nla l'awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara wa lori ileeṣẹ aṣọ tijọba ipinlẹ naa ṣẹṣẹ kọ pari lati pese iṣẹ f'awọn ti ko niṣẹ lọwọ, paapaa awọn ọdọ.
 
Ileeṣẹ naa ti wọn pe ni Kwara State Garment Factory jẹ ọkan lara awọn akanṣe iṣẹ tijọba Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq dawọ le lati pese iṣẹ f'awọn eeyan.
 
Nibẹ ni wọn yoo ti maa ṣe aṣọ loriṣiriṣi, eyi ti yoo mu ilọsiwaju alailẹgbẹẹ ba eto ọrọ aje ipinlẹ naa, nibi ti awọn eeyan kaakiri agbaye yoo ti maa wa ko aṣọ lọpọ yanturu.

Oriṣiriṣi irinṣẹ igbalode ti wọn fi n ṣe aṣọ lagbaye lo ti wa ninu ọgba ileeṣẹ naa, eyi ti yoo mu ipese aṣọ ṣiṣe rọrun f'awọn oṣiṣẹ.

















No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI